Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti padà sí ìlú Abuja lẹ́yìn ìsinmi ọ̀sẹ̀ méjì gbáko ni Daura ni ìpínlẹ̀ Katsina.
Pápákọ̀ òfurufú ti Nnamdi Azikiwe ni ìlú Abuja ni Ààrẹ dé sí, ní ọjọ́ ajé pẹ̀lú ọgá àgbà pátápátá fún àwọn òṣìṣẹ́, ọ̀mọ̀wé Ibrahim Gambari pẹ̀lú Mínísítà fún ìlú Abuja Mohammed Bello
Ààrẹ kuro ni ìlú Abuja ni ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù Kejì láti lọ dìbò, ààrẹ to waye ni ọjọ́ karùn-ún dinlọgbọn osu ọdún yìí.