Take a fresh look at your lifestyle.

U-20 AFCON: Mínísítà fún ìdárayá gbóríyìn fún Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n gba Fàdákà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 117

Mínísítà fún ìdàgbàsókè ọ̀dọ́ àti ìdárayá, Sunday Dáre, ti gbóríyìn fún Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Flying Eagles, fún ipò kẹta tí wọ́n ṣe nínú ìdíje ife orílẹ̀-èdè Adúláwọ̀ (AFCON),U–20,ní Egypt.

Flying Eagles lu ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Young Carthage Eagles ti Tunisia, ní àmìn mẹ́rin sí óódo,lọ́jọ́ Ẹtì láti gba Fàdákà.

Dáre, nínú àlàyé kan tí ó fi síta nípasẹ̀ olùránlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Tóyìn Ìbítóyè, sọ pé Fàdákà náà dára ju àìrí ìkankan gbà lọ.

Mínísítà wá rọ ẹgbẹ́ náà láti lo ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́ nínú ìdíje náà lọ́nà tó tọ́,gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń múra fún ìdíje ife àgbáyé FIFA  Under-20, ní Indonesia,ní oṣù karùn ún.

Ife àgbáyé FIFA U-20, yóò bẹ̀rẹ̀ láàrin ogúnjọ́,oṣù karùn ún sí ọjọ́ kọkànlá,oṣù kẹfà,ní orílẹ̀-èdè Indonesia.

Leave A Reply

Your email address will not be published.