NEMA pín àwọn oun èlò ìtura fún àwọn olùfaragbà omíyalé ní ìpínlẹ̀ Kánò
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé iṣẹ́ tó ń rísí ìṣàkóso pàjáwìrì lórílẹ̀-èdè (NEMA), pẹ́lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ilé-iṣẹ́ tó ń rísí ìṣákóso pájáwìrí ní ìpínlẹ̀ Kánò (SEMA), ti pín àwọn ohun èlò ìtura fún àwọn olùfaragbà ìjàǹbá iná àti omíyalé ọ̀tà-dín-lẹ́ẹ́ẁá-lé-nígba,ní ọjọ́ Àìkú,ní ìpínlẹ̀ náà.
Alákóso agbègbè ọ́fíísì NEMA Kánò/Jìgáwá, Dókítà Nuradeen Abdullahi, sọ pé pínpín yìí jẹ́ ara akitiyan ìjọba àpapọ̀ láti ran àwọn olùfaragbà jákèjádò orílẹ̀-èdè lọ́wọ́. Abdullahi, tí Adarí Ìṣirò NEMA ti Kánò , Mr Rilwan Isma’il,ṣojú rọ àwọn tó jàǹfànì náà láti lò wọ́n dáradára.
Akọ̀wé aláṣẹ SEMA, Dókítà Saleh Jili, sọ pé àwọn oun ìtura yìí wà fún ìtùnú àwọn olùfaragbà.
Ó sọ pé àwọn oun ìtura náà ni àpo àgbàdo,òrùlé,ẹní,Bùláńkẹ́kì,ibùsùn,ike ìpọnmi,iyọ̀, nkàn ìlò ilé ìtura,aṣọ àti nẹ́étì ẹ̀fọn.