Olùdíje gómìnà fún ẹgbẹ́ òṣèlú Young Progressive YPP, ní ìpínlẹ̀ Ebonyi, iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, Dókítà Sunday Opoke ti takú pé òun kò ṣèjàǹbá ẹgbẹ́ òun o, láti ṣàtìlẹyìn fún olùdíje ipò gómìnà fún ẹgbẹ́ All Progressive Congress, APC.
Dókítà Opoke ṣe àlàyé yìí nígbà tí ó ń báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀,ní Abákáliki,olú-ìlú ìpínlẹ̀.
Ó ní òun kò ju èròńgbà òun láti di gómìnà ìpínlẹ̀ náà nù,láti kàn ṣàtìlẹyìn fún olùdíje mìíràn.
Ó wá rọ àwọn ènìyàn ìlú náà láti tú yáyá,túyàyà dìbò fún òun nínú ìbò gómìnà tí ó ń bọ̀ lọ́nà,láti mú àlàáfíà bá gbogbo agbègbè ìpínlẹ̀ náà.