Ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Isreal ti ṣe ìwọ́de tó lágbára jùlọ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè náà.
Ìwọ́de lórí ìgbésẹ̀ ìjọba fún àtúnṣe tipátipá lórí ètò ìdájọ́ ti ń lọ lọ́wọ́ fún bíí ọ̀sẹ̀ mẹ́wàá báyìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ afẹ̀hónúhàn ló jáde ní àwọn ìlú bíi Haifa, tí àwọn tó tó igba ẹgbẹ̀rún sì tú síta ní Tel Aviv.
Àwọn alárìí-wísí sọ pé àtúnṣe náà yóò jin ìjọba tiwantiwa lẹ́sẹ̀.Sùgbọ́n ìjọba Benjamin Netanyahu sọ pé ìgbésẹ̀ tí ó dára jùlọ fún àwọn olùdìbò ni.
Adarí alátakò, Yair Lapid sọ fún àwọn èrò ní iwọ̀ oòrùn ìlúu Be’er sọ pé orílẹ̀-èdè ń kojú “làásìgbò tó lágbára jùlọ nínú ìtàn”.