Gómìnà Bauchi gbé Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà sílẹ̀ fún àwọn olùfaragbà ọjà tó jóná
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi , Bala Mohammed Abdulkadir ti kéde gbígbé iye owó Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà sílẹ̀ fún àwọn olùfaragbà ọjà tó jóná láìpẹ́ yìí,ní ọjà Múdà Lawal,ní ìpínlẹ̀ náà.
Muda Lawal, jẹ́ ọ̀kan lára ọjà tó tóbi jùlọ ní olú ìlú náà, tí àwọn ènìyàn ti ń pàdé lójojúmọ́ láti àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn,fún kátàkárà.
Iná jó ọjà náà láàrin òru,tí ó sì jó àwọn ìsọ̀ léyìí tí ó mú wọn pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mílíọ́nù Náírà àti àwọn dúkìá tí kò ṣeé díyelé.
Gómìnà wá pinnu pé ìjọba yóò tún àwọn ibi tí iná náà jó kọ́ àti ìpèsè ohun ìtura ní kíákíá fún àwọn olùfaragbà láti tẹ̀síwájú àti láti padà sípò.