Arábìnrin àkọ́kọ́ ìpínlẹ̀ Sókótó, Hajiya Mariya Tambuwal pè fún ìdìbò gómìnà àti aṣojú ṣòfin ìpínlẹ̀ nírọ̀rùn,ní ọjọ́ kejìdín-lógún,oṣù kẹta.
Ìyáàfin Tambuwal pe ìpè yìí níbi àpèjọ ìpòlongo ní agbègbè iwọ̀ oòrùn Sókótó,tí ikọ̀ àwọn obìnrin ẹgbẹ́ PDP ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Aya gómìnà náà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ náà,bí wọ́n ṣe tú yàyà,tú yáyá láti dìbò ààrẹ àti ti ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin àpapọ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.
Tambuwal, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Aisha Madawaki, Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ gíga ṣojú,wá rọ àwọn obìnrin kí wọ́n mójútó àwọn ọmọ wọn láti má jẹ́ kí wọ́n tàn wọ́n sí ìwà jàgídíjàgan lásìkò ìdìbò.
Ó túnbọ̀ wá rọ àwọn obìnrin PDP àti ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ náà láti ṣe ojúṣe wọn nínú ìdìbò tó ń bọ̀ yìí,fún àṣeyọrí ìbò wọn.