Take a fresh look at your lifestyle.

A le lo ẹ̀rọ alágbèéká wa fún ìkìwọ̀ ìwà ipá abẹ́lé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 84

Ẹgbẹ́ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀tọ́ ọmọdé àti àwọn obìnrin (OPACTS), ti rọ àwọn obìnrin láti lo ẹ̀rọ alágbéká wọn gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ fún ìkìwọ̀ ìwà ipá abẹ́lé.

Olùdarí aláṣẹ ti ilé-iṣẹ́ tí kìí ṣe tìjọba náà (NGO), Ayọ̀ọlá Olúṣẹ́gun, ṣe àlàyé yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn obìnrin ìgbèríko ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọ̀nà mìíran láti ṣe ìkìwọ̀ ìwà ipá tí àwọn obìnrin ń kojú.

Olúṣẹ́gun sọ pé nígbà tí àwọn ẹ̀rọ alágbéká ń ṣiṣẹ́ ní àwọn agbègbè ìgbèríko,gẹ́gẹ́ bíí àwọn ìlú,kí àwọn obìnrin lo àǹfàní rẹ̀ láti kojú ìwà ipá abẹ́lé.

Ó wá rọ àwọn obìnrin láti máa lo ẹ̀rọ alágbéká wọn láti gba àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá sí wọn àti àwọn ọmọdé sílẹ̀, kí wọ́n sí fi ránṣẹ́ sí àwọn alákòóso tó tọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

Leave A Reply

Your email address will not be published.