Àwọn ọdọ Teranga Lions tí Senegal lú aladugbo rẹ̀ Gambia ní ọjọ́ Àbámẹ́ta látí gbà ìfé TotalEnergies U-20 Africa Cup of Nations.
Àmì ayò látí ẹ̀sẹ Sulaymane Faye àtí Mamadou Camara ní Olú-ìlú Egypt ní Cairo ló mú Senegal bórí Ìfẹsẹwọnsẹ́ náà.
Senegal, Orílẹ̀-èdè ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tó peregede sí ìpele aṣekagba ní ọjọ́ Àbámẹ́ta láì pàdánù Ìfẹsẹwọnsẹ́ kankan.
Tún kà nípa:CAF Tún Ṣí Ayé Sílẹ̀ Fún Ìgbálejo AFCON 2025
Àwọn ọdọ Teranga Lions ló ń gbá bọ́ọ̀lù ìparí ní ìgbà kẹ́rin nínú ìdíje TotalEnergies U-20 AFCON lẹyìn tó tí dé bẹ̀ ní ọdún 2015, 2017 àtí 2019.