Take a fresh look at your lifestyle.

Ruffai Ni Yóò Sojú Ààrin Gbìngbìn Kano : Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ

0 70

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jùlọ ní Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà ti fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ ní ọjọ́ Ẹtì pé Mallam Ruffai Hanga ni sẹ́nétọ̀ tí wọ́n dìbò yàn tí yóò sojú ààrin gbìngbìn Kano ní abẹ́ àsìá ẹgbẹ́ NNPP.

 

Ilé Ẹjọ́ Gíga fagilé àwíjàre Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀rí, Ibraheem Sekarau gẹ́gẹ́ bí olùdíje sí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Àgbà lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú NNPP. Èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n osù kejì.

 

Adájọ́ Àgbà náà tẹ̀lé ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga àti Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ìlú Abuja ti dá tẹ́lẹ̀, èyí tí ó sàfihàn Ruffai gẹ́gẹ́ bí olùdíje tòótọ́.

 

Èyí ti wá mú wàhálà asojú ààrin gbìngbìn kano sí Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Àgbà dópin nínú ìdìbò tí ó wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n osù kejì.

Leave A Reply

Your email address will not be published.