Àjọ tí ó ń mójútó ìpèsè omi fún lílò ní Abuja ti kéde ìdádúró ọlọ́jọ́ méjì ní àgbègbè náà.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ náà se sọ, ìdádúró náà wà fún ìsàtúnṣe àwọn ohun èlò fún ìpèsè omi.
Àwọn àgbègbè tí àtúnṣe náà yóò wáyé ni, Utako, Life camp, Jabi, Gwarimpa, Wuye, Mabushi, Apo, Durumi, Games Village, àti Galadimawa.
Ìrètí wà pé ìpèsè omi lákọ̀tun yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlá osù keta. Àjọ náà wa pàrọwà sí ará ìlú, lórí ìpalára tí ìsẹ̀lẹ̀ kékeré náà yóò múwá.
[…] Tún kà nípa:Ìbùmu-Bùwẹ̀ Omi Yóò Dúró Fún Ọjọ́ Méjì Ní Ìlú Abuja […]