Take a fresh look at your lifestyle.

Ènìyàn Méjìlélọ́gbọ̀n Gba Ìtúsílẹ̀ Nínú Àwọn Tí Ó Fara-Káásá Ìsẹ̀lẹ̀ Jàm̀bá Ọkọ̀ Ojúurin

0 244

Alákòsóo Ètò ìlera ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Ọ̀jọ̀gbọ́n Akin Abayọmi sàlàyé pé kò dí ní méjìlélọ́gbọ̀n àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìsẹ̀lẹ̀ láabi ọkọ̀ ojúurin ni ó gba ìtúsílẹ̀ láti ilé ìwòsàn.

 

Abayọmi sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Ẹtì nígbà tí ó ń sàlàyé nípa ìsẹ̀lẹ̀ náà. Ó sọ wípé ènìyàn méjìlélọ́gọ́rùn-ún ni ó fi ara pa tí àwọn mẹ́fà sì pàdánù ẹ̀mí nínú wọn. Ó wá fi àrídájú léde wípé, àwọn tí ó kù wà ní ipò ìlera tí ó dára.

 

Ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi gbóríyìn fún àwọn tí ó fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn tí ọ̀rọ kàn, ò wá se àfirinlẹ̀ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ni yóò janjú ètò ìtọ́jú gbogbo àwọn tí ó ní ìpalára.

Leave A Reply

Your email address will not be published.