Take a fresh look at your lifestyle.

Ọwọ́ Sìnkún Àjọ EFCC Tẹ Gbajúgbajà Oníṣòwò Kan Ní Ìlú Ìbàdàn Lórí Ẹ̀sùn Jíbítí Mílíọ̀nù Mẹ́sàn-án Náírà

0 93

Panpẹ Àjọ to n rí sí ṣíṣe owó ìlú kumọkumọ, EFCC ẹkùn tí Ìbàdàn, tí gbé arákùnrin kan, Odeleye Moses Oluwabusola àti ilé iṣẹ wá sí iwájú Onídàájọ Mohammed Owólabí ní Ilé Ẹjọ́ Gíga to jókòó ní ìlú Ìbàdàn lórí ẹsun to da lórí ṣiṣe ẹda, ayédèrú ìwé àti gbígba owó lọnà àìtó.

Àtẹ̀jáde kan ti akọwe ẹka ìròyìn fún Àjọ EFCC ẹkùn tí Ìbàdàn, ni ipinlẹ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Wilson Uwujaren fi síta fún àwọn akọroyin lo sàlàyé àwọn ẹsun ti àjọ EFCC fi kan Ọgbẹni Odeleye.

Gẹgẹ bi ìwádìí ṣe fi ìdí rẹ mule, Ọgbẹni Owólabí tó ní ilé iṣẹ ‘Beedel Strategic Investment Company Nigeria Limited’ lo tọ Ololade Desmond-Eke lọ pẹlú ayédèrú ìwé ọja láti yá owó tó tó Mílíọ̀nù Mẹsan Náírà (N9,000,000.00) pẹlu ele orí rẹ tíì ṣe N495,000.00, pẹlu àlàyé àti àjọsọ wí pé òun fẹ́ fi owó náà ṣe àwọn iṣẹ àkànṣe ti ilé iṣẹ́ rẹ̀ gbà káàkiri Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣugbọn tí olupẹjo wa ṣe àkíyèsí pé ayédèrú ìwé ní olujẹjo náà fi gba owó.

Nígbà ti olujẹjo ra ọwọ ẹbẹ sí ilé ẹjọ wí pé òun kò jẹbi àwọn ẹsun ti ilé ẹjọ́ fi kàn òun pẹlu àlàyé. Nítorí náà, Agbẹjọro fún ìjọba, Oyelakin Oyediran fi tó ilé ẹjọ́ létí wí pé òun ti ṣetán láti bẹrẹ ìwádìí.

Ṣugbọn, Agbẹjọro fún olujẹjo, Sikiru Adewoye sọ fún ilé ẹjọ́ láti pàṣẹ fún agbẹjọro ìjọba láti ṣe àfihàn àwọn ẹri tó tọ́ka sí ẹsun ti ilé ẹjọ fi kàn olujẹjo náà, tó sì tún bẹ ilé ẹjọ́ láti fún olujẹjo náà ni òmìnira láti máa lọ ilé ko ba lè máa ti ilé wa jẹ́ jọ ni ile ẹjọ́.

Agbẹjọro fún ìjọba, Oyediran wá ta ko ìbéèrè Agbẹjọro fún olujẹjo latari pé olujẹjo náà lè sálọ nítorí onírúurú ẹsun ọdaràn to rọ mọ ọ lẹsẹ ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlè Ọ̀yọ́ àti ilé ẹjọ́ gíga apapọ ni ìlú ìbàdàn.

Leyin tí Onídàájọ Owólabí ti gbọ àlàyé àwọn agbẹjọro méjèèjì, o pàṣẹ ki ile ẹjọ fi olujẹjo náà sì àhámọ́ ti ilé ẹjọ di sun igbejo sí ọjọ Kẹrinla oṣù yìí.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.