Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Fún Eré Ìdárayá Rọ Ikọ̀ Flying Eagles Láti Ní Àfojúsùn Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé

0 168

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àti Eré Ìdárayá, Sunday Dáre, ti rọ ikọ̀ Flying Eagles láti dojú ìfojúsùn wọn kọ ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń bọ̀ lọ́nà; Kí wọ́n gbàgbé ìjákulẹ̀ ayò kan sí òdo (1-0) tí ikọ̀ wọn pàdánù sí ọwọ́ ikọ̀ ti Gambia ní ìdíje Africa Cup of Nations (AFCON) tí ọjọ́ orí wọn kò ju ogún odún lọ.

Ògbẹ́ni Dare sọ èyí ní ọjọ́ Isẹ́gun, ó kẹ́dùn pé ikọ̀ Flying Eagles kò leè kópa nínú àsekágbá ìdíje náà sùgbọ́n Ó gbóríyìn fún wọn látàrí pé wọn gba tíkẹ́ẹ̀tì láti  lọ fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Ikọ̀ Nàìjíríà yóò kojú ikọ̀ ti Tunisia ní ọjọ Ẹtì láti mọ ẹni tí yóò ṣe ipò kẹta. Ikọ̀ Senegal lo lù ikọ̀ tí Tunisia ni àlùbomi ayò mẹ́ta sí òdo (3-0) tí àwọn náà fi já kulẹ̀ láti má leè wọ ipele àsekágbá.
Ikọ̀ Orílẹ̀-èdè Senegal àti Gambia ni yóò jo wọ̀yá ìjà ní abala àsekágbá ní ọjọ́ Àbámẹ̀ta.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.