Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Arówósafé, ti ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ sí Bàbá Fádèyí Olóró ti jáde láyé.
Ọmọbìnrin Fádèyí Olóró, Bídèmí Olúwáfúnkẹ́ fi ìdí ìròyìn náà múlẹ ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun lórí aago.
Ó sọ ní àìpẹ́ yí lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan nípa oun tí bàbá rẹ̀ ń là kọjá. Bí ó se sọ, àìsàn to jẹ mọ́ kídìnrín àti nǹkan míràn ló ń bá bàbá òun fínra bí àyẹ̀wò se fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láti ilé ìwòsàn University College Hospital (UCH).
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san