Ẹ San Owó Ìrìn Àjò Hajj Yín Títí Ogúnjọ́ Oṣù Yìí: Àjọ Tó Ń Ṣe Kòkárí Ìrìn Àjò Hajj Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Àjọ to n ṣe kokari irin àjò lọ sí ilẹ mímọ (Ẹka ti Musulumi) tí jẹ kí o di mímọ pé òun yóò ṣiwọ gbígba ìdá kínní owó asan silẹ fún irin àjò hajj ti ọdún 2023 ní Ogunjọ oṣù yìí.
Eléyìí lo jẹyọ nínú ọrọ Alága Àjọ náà, Ọjọgbọn Sayed Malik gẹgẹ bí o ṣe sàlàyé fún àwọn akọroyin ni ìlú ìbàdàn, ni ìpínlè Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nígbà tí Àjọ náà fi gbedeke Milionu Meji o le mẹfa Náírà (N2.6M) gẹ́gẹ́ bíi owó akọsan fún ẹni kọọkan ọmọ Ìpínlè Ọ̀yọ́ tó fẹ láti lọ irin àjò hajj ti ọdún 2023
O fi àsìkò náà mú wá sí ìrántí awọn ti o fẹ darapọ̀ mọ́ ìrìn àjò náà pé, Àjọ to n ṣe kokaari ìrìn àjò Hajj ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (NAHCON) ti yọnda ààyè ijoko 1,441 fún ìrìn àjò Hajj ọdún 2023 fún Ìpínlè Ọ̀yọ́, ti Àjọ Hajj ní Ìpínlè Ọ̀yọ́ sí ti sàlàyé ki ẹni kọọkan san (N2.6M) owó ṣáájú àsìkò ti Àjọ NAHCON yóò kéde iye owó tí ẹni kọọkan yóò máa san.
Alága Àjọ Hajj ni ìpínlè Ọ̀yọ́ wa tun fi àsìkò náà ké sí gbogbo àwọn tí kò ti san owó asan silẹ tabi ti ko ti san owó tó tó iye owó asan silẹ láti yára ṣe bẹẹ sí inú àpò ilé ifowopamọ tí wọ́n ti ya s’oto fún kò to di Ogunjọ oṣù kẹta ọdún yìí kí ànfààní náà má bàá fò wọn ru.
Nígbà tí o n dupẹ lọwọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde lórúko Àjọ náà, Ọjọgbọn Malik fi emi imore hàn sí Gómìnà fún atilẹyin rẹ nípa bí o ṣe rí dájú wí pé gbogbo ètò ló ti wa ni kalẹ láti ri dájú pé ìrìn àjò hajj ọdún yìí lọ bo ṣe yẹ.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply