Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Eswatini Fi Àrídájú Àjọṣepọ̀ Olóṣèlú Hàn Fún Orílẹ̀-èdè Taiwan

0 171

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Eswatini, Cleopas Dlamini ti sọ pé àjọṣepọ̀ tó dára nípa ètò ìlú sí wa láàárín orílẹ̀-èdè òun àti ti Taiwan, orílẹ̀-èdè òun kò sí níbi ọ̀rọ̀ àbùkù tàbí ìbínú sí orílẹ̀-èdè Taiwan rárá.

Ọ̀gbẹ́ni Dlamini wà dupe lọ́wọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Taiwan fún ìrànlọ́wọ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí wọ́n ti ń se fún orílẹ̀-èdè Eswatini.

Ìròyìn ró pé orílẹ̀-èdè Eswatini nìkan ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti ọ̀kan soso nínú  orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá káàkiri àgbáyé tó ti ní ìbásepọ̀ ọ̀lọ́jọ́ pípẹ́ ninu ọ̀rọ̀ ètò ìlú pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Taiwan tí orílẹ̀-èdè China kà kún ẹ̀yà tó ti yapa.

Orílẹ̀-èdè Taiwan àti Eswatini yóò ṣe ayẹyẹ àjọṣepọ̀ wọn ọlọ́dún márùn ún dínlọ́gọ̀ta nínú osù kẹsàn án ọdún yìí.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button