Ẹlẹ́sèayò Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù ikọ̀ Manchester United, Marcus Rashford ti fi lédè pe ikọ̀ òun kò sọ ìrètí nù nínú ìdíje àlùbami tí ìkọ̀ ti Liverpool lù wọ́n bí ejò àìjẹ ní ayò méje sí òdo. Ó wí pé, ikọ̀ òun kò gbọ́ ara wọn yé bótiyẹ lórí pápá ló fàá.
Ìdíje náà bá àkọsílẹ̀ rere tí ìkọ̀ Manchester United ni nítorí pé ikọ̀ kankan kò ti lù wọ́n nínú ìdíje mọ́kànlá ti wọ́n ti gbà sẹyìn. Ọdún 1931 ni irú èyí ti ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà tí ikọ̀ Wolverhampton Wanderers po ẹ̀kọo ìbànújẹ ayò méje sí òdo bákan náà fún wọn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san