Take a fresh look at your lifestyle.

IWD 2023: Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra Gbósùbà Fún Àwọn Obìnrin A Mú Ìlú Dàgbà Sókè.

0 61

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra ọ̀mọ̀wé Chukwuma charles Soludo ti sọ ipa ti àwọn obìnrin n kò nípa Ìdàgbàsókè Ìlú gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ṣe fọwọ́ rọ sẹ́yìn.

Gómìnà Soludo sọ èyí nínú àtẹjáde láti ọwọ́ Akọ̀wé rẹ, ni ọjọ́ ayẹyẹ àyájọ́ awọn obìnrin tó wáyé ni ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹta ọdún 2023.

Gómìnà àti ìyàwó rẹ, parapọ̀ láti sá jọ yọ pẹlu awọn obìnrin ìpínlẹ̀ Anambra fún ipa ma ni gbàgbé ti wọn kò fún ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní o jẹ ànfààní nla fún oun lati bá àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ náà ṣiṣẹ pọ, o sí dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún àtìlẹ́yìn wọn ti ko lẹgbẹ.

O ṣe ìlérí wí pé Ìjọba rẹ yóò tèsíwájú lati ma gbárùkù tí àwọn obìnrin ìpínlẹ̀ náà.

Leave A Reply

Your email address will not be published.