Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà yóò gba àmìn ẹ̀yẹ ní Maldives

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 170

Wọn yóò dá Mínístà Nàìjíríà fún eré ìdárayá àti ìdàgbàsókè ọ̀dọ́, Ọ̀gbẹ́ni Sunday Dáre lọ́lá pẹ̀lúàmìn ẹ̀yẹ pàtàkì’ ní orílẹ̀-èdè Maldives.

Èyí jẹ́ fún ìmọ rírì ipa tÍ ó kó nínú ìdàgbàsókè eré ìdárayá ní Nàìjíríà àti ní Agbègbè Adúláwọ̀.

Mínísítà fún ọ̀dọ́,eré ìdárayá àti ìrónilágbára agbègbè,ti orílẹ̀-èdè Maldives, Ahmed Mahloof, ló sọ èyí pé kìí ṣe pé wọ́n dá  Sunday Dare lọ́lá yìí nítorí ipa tó kó nínú ìdàgbàsókè eré ìdárayá ní Nàìjíríà,sùgbọ́n ní agbègbè Adúláwọ̀ lápapọ̀.

Ayẹyẹ náà yóò wáyé ní orilẹ̀-èdè Maldives,ní ọjọ́ kẹrìndín-lógún,oṣù kẹta 2023; tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Maldive, Ibrahim Mohamed Solih, àwọn gbajúgbajà eléré ìdárayá pẹ̀lú àwọn eléré ìdárayá orílẹ̀-èdè náà àti àwọn mìíràn yóò wà níkàlẹ̀ níbi ayẹyẹ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button