U20 AFCON 2023: Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Gbà Flying Eagles Níyànjú Láti Gbé Ìfé Náà Wálé
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Ààrẹ Muhammadu Buhari tí gbà àwọn àgbábọ́ọ̀lù Flying Eagles níyànjú láti gbà ìfé ìdíje CAF U-20 Africa Cup of Nations (AFCON) tó ń lọ lọ́wọ́ ní Egypt.
Flying Eagle yóò kojú Gambia lóni ní ìpele aṣekagba tí ìdíje náà pẹ̀lú bí wọ́n tí ṣé peregede látí kópa nínú ìfé Àgbáyé FIFA U20 World Cup ṣé tí wà nilẹ̀.
Ààrẹ Buhari ránṣẹ sí ẹgbẹ́ náà, bí Mínísítà àwọn ọdọ àtí èrè ìdárayá Sunday Dare tí bálẹ̀ sí Cairo ní ọjọ́ Àìkú pẹ̀lú àgbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹlẹ rí àtí olùrànlọwọ sí Ààrẹ, Ọ̀gbẹ́ni Daniel Amokachi, ṣé ìwúrí fún Flying Eagles látí fọkansi sí ẹbùn tó gá jùlọ nínú ìdíje náà.
Tún kà nípa: 2023 U20 AFCON: Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Flying Eagles Yóò Ní Ìpàgọ́ Ìgbáradì Ní Òkè-òkun Ní Oṣù Kínní
“Ààrẹ àtí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìgbàgbọ nínú àṣeyọrí yín. Ìdí níyì tí Ààrẹ fí pàṣẹ fún mí látí wà yọjú sí yín. Lóòótọ́, tikẹẹti ife àgbáyé ló jẹ́ dandan ṣùgbọ́n ní báyìí, ìfé náà tí ṣé dandan.