Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Pàdánù Ẹ̀mí Látàrí Àìsàn Lassa Tí Ó Súyọ

0 142

Kò dí ní ènìyàn márùndíláàdọ́run tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́fà nínú ọdún 2023. Ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ìpínlẹ̀ ogún léyìí tí ó sì kárí ìjọba ìbílẹ̀ mọ́kàndílọ́gọ́rin ní àwọn ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí àjọ tí ó ń gbógun ti ìtànkálẹ̀ àrùn se sọ.

 

Àjọ náà fi léde wípé àwọn afurasí tí ó ní àìsàn náà lé ní ẹgbẹ̀rún méjì, nígbà tí àwọn tí ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ti fojú hàn. Àjọ náà wá sàlàyé pé ènìyàn márùndíláàdọ̀rin ni ó ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra láàrin osù mẹ́fà.

 

Lára àwọn ìbílẹ̀ tí ọ̀rọ̀ náà kàn ní Ondo, Edo, Bauchi, Taraba, Ebonyi, Gombe, Nasarawa àti Plateau.

 

Àmọ́sá, ìjọba ti gbáradì láti gbógun ti àìsàn náà tí ìrètí sì wà pé yóò di àfìsẹ́yìn tí egúngún ń fi asọ láìpẹ́.

Leave A Reply

Your email address will not be published.