Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Àtí Íńdíà Ṣe Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Lórí Ìwádìí Ìmọ-jinlẹ̀ Ojú-ọjọ́ Àtí Ìdàgbàsókè

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

1 266

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìjọba orílẹ̀-èdè India tí fọwọ́ sí ìwé àdéhùn (MoU) fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lórí iṣẹ́ ìmọ-jinlẹ̀ ojú-ọjọ́, ìwádìí ìmọ-ẹrọ àtí ìdàgbàsókè.

Àdéhùn náà ní a fọwọ́ sí ní orúkọ Ilé-iṣẹ́ Oju-ọjọ Nàìjíríà (NiMet) nípasẹ̀ Olùdarí rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mansur Matazu àti Dókítà Mrutyunjay Mohapatra, Olùdarí tí Ẹka Ojú-ọjọ́ India (IMD), làkókò ìpàdé àwọn aláṣẹ ìgbìmọ̀ tí World Meteorological Organisation (WMO) ní Geneva, Switzerland.

Àwọn àgbègbè mìíràn ti àbá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ náà pẹ̀lú; Ìwádìí ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì lórí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ojú-ọjọ́ àtí àwọn òun èlò rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà mìíràn, ‘bí ó tí ń ṣẹ̀lẹ̀’ àtí àwọn ìmọràn lẹ́sẹkẹ́sẹ àtí àgbàrá ìkọ́ni.

Tún kà nípa:Ìjọba Àpapọ̀ Bu Ọwọ́ Lu Àdéhùn (MOU) Pẹ̀lú Ilé-Iṣẹ́ Huawei Technologies Nigeria Limited Lórí Ìmọ̀-Ẹ̀rọ Ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Àwọn Orílẹ̀-èdè méjèèjì tún ríi dájú pé irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yìí gbọ́dọ̀ ní àwọn òfin, ìlànà àti àwọn àdéhùn mìíràn bí ìjàbọ̀ ọlọdọọdun tó bá àjọ Àgbáyé mú èyí tí àwọn méjèèjì yóò buwọ́lù.

Ibuwọlú ìwé àdéhùn náà wà ní ìrètí látí jẹ́ kí ibaṣepọ àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì gbópan sí.

One response to “Nàìjíríà Àtí Íńdíà Ṣe Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Lórí Ìwádìí Ìmọ-jinlẹ̀ Ojú-ọjọ́ Àtí Ìdàgbàsókè”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button