Gbajúgbajà ajó bí òkòtò, Kaffy ti gba àwọn obìnrin nímọ̀ràn láti máa jó lóòrè-kóòrè.
O fí ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó ń sàlàyé ànfààní tí ijó jíjó ń se lagọ̀-ara, níbi ayẹyẹ ijó fún àwọn Obìnrin ti ọdún 2023, èyí tí ó wáyé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrin osù kẹta ní ìlú Èkó. Kaffy tẹ̀síwájú pé, ijó jíjó máa n gbé ìrònù kúrò lára, ó maá ń mú ara jí pépé, ó sì máa ń jẹ́ kí ẹ̀yà ara ṣisẹ́ dára-dára.
Arábìnrin Kaffy tún sọ wípé ìlera lòògùn ọrọ̀ àtipé àwọn obìnrin nílò ìdárayá ní gbogbo ìgbà láti dènà àìsàn, ó wá gbàwọ́n níyànjú láti máa jó ní gbogbo ìgbà fún àlàáfíà ara àti ọkàn.
Ajó bí òkòtó náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wípé, ijó jíjó jẹ́ ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìgbe ayé rere, ìdùnnu, àlàáfíà ara àti ìgbáyégbádùn ẹ̀mí.