Olùgbé ìlú Gital ní ìjọba ìbílẹ̀ Tafawa Balewa, ìpínlẹ̀ Bauchi ti pàrọwà sí ìjọba fún ìpèsè omi ẹ̀rọ lójúnà àti tán ìsòro ọ̀wọ́ngógó omi.
Olórí ìlú Gital, Alhaji Umar Aliyu pe ìpè náà nígbà tí àjọ tí ó ń sàkóso ọ̀rọ̀ omi sàbẹ̀wò sí ààfin rẹ̀. Ó sàlàyé pàtàkì iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí ipa tí omi ń kó nínú ìgbé ayé ọmọnìyàn àtipé tí ìgbésẹ̀ náà bá wáyé, yóò dènà àkọlù àìsàn tí ó ń wáyé láti ara omi.
Ó wá rọ àjọ náà fún ṣíse ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ omi àti àmójútó ètò tí ìjọba ti se sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ omi.