Gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa, Abdullahi Sule ti sèkìlọ̀ fún àwọn olórí ẹ̀sìn láti jìnà sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè dá wàhálà sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó se ìpàdé pàjáwìrì pẹ̀lú àwọn olórí ẹ̀sìn ní ọ́ọ́fìsì Gómìnà ní ìlú Lafia, olú ìlú ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Gómìnà sàlàyé pé ìpàdé pàjáwìrì náà wáyé látàrí fán-án rán kan tí ó wà lórí ẹ̀rọ ayélujára léyìí tí ó jáde lẹ́yìn ìdìbò àpapọ̀, tí ó sì le è da omi àlàáfíà ìlú rú. Ó pèpè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ará ìlú àtipé kí wọ́n jìnà sí ọ̀rọ̀ tí ó le è dà rògbòdìyàn sílẹ̀.