Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ Jẹ́ Kí Àbájáde Èsì Ìdìbò Gbogbogbòò Jẹ́ Àtẹ́wọ́gbà- Sẹ́nétọ̀ Bent

0 156

Sẹ́nétọ̀ Grace Bent ẹni tí ó sojú Gúsù Adamawa ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ ti ìlú Abuja ti pàrọwà sí olùdíje lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òsèlú P.D.P, Alhaji Atiku Abubakar àti Ọgbẹ́ni Peter Obi ti ẹgbẹ́ òsèlú LP láti gba àbájáde èsì ìdìbò àpapọ̀ tí ó wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n osù kejì wọlé, àtipé fífìdí rẹmi wọn jẹ́ ara òsèlú.

 

Bent fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní ìlú Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa nígbà tí ó ń kí Ààrẹ tuntun tí wọ́n dìbò yàn Bọla Ahmed Tinubu àti igbákejì rẹ̀ sẹ́nétọ̀ Kashim shettima fún ìjáwé olúborí wọn.

 

Ó sàlàyé síwájú pé lílọ sí Ilé-Ẹjọ́ láti tako àbájáde èsì ìbò náà jẹ́ ìfàsìkò àti ìfowó sòfò nítorí pé ètò ìdìbò náà fojúhàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó peregedé jùlọ.

 

Ó sàfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé  rẹ̀ nínú ìjọba tí ó ń bọ̀, Ó sì fi àrídájú hàn pé ìjọba náà yóò mú ayé rọrùn fún mùtúmùwà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button