Ààrẹ Buhari sèdárò pẹ̀lú arábìnrin Maryam Abacha àti ìdílé rẹ̀ lórí ikú Abdullahi tí ó jẹ́ ọmọbíbí ọ̀gágun olórí orílẹ̀ èdè tẹ́lẹ̀rí, Abacha.
Ààrẹ sàpèjúwe ìsẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lágbára, Ó sì sèdárò lórí ikú olóògbé náà.
Ó wá gbàdúrà pé kí elédùmarè rọ́ ìdílé náà lójú, kí ò sì tìlẹ̀kùn irú ìsẹ̀lẹ̀ láabi bẹ́ẹ̀.