Kọmíṣọ́nà ìpínlẹ̀ Anambra pè fún ìrànlọ́wọ́ fún ètò ìlera alábọ́ọ́dé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Kọmíṣọ́nà fún ìlera ti ìpínlẹ̀ Anambra , Dókítà Afam Obidike,ti rọ àwọn ènìyàn,agbègbè láti ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba láti ṣe ìmúdúró ètò ìlera tó múnádóko àti èyí tó ṣeé gbára lé,tí yóò sì wà lárọwọ́tó àti tí yóò jẹ́ alábọ́ọ́dé fún gbogbo ènìyàn.
Obidike pe ìpè yìí nígbà tí ó ń ṣí ilé-ìwòsàn St. Michael,ní Onono, Umuikwu , iwọ̀ oòrùn ìjọba ìbílẹ̀,ní ìpínlẹ̀ Anambra.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ náà, Kọmíṣọ́nà tí ó ṣàlàyé pé Gómìnà Chukwuma Soludo, ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ri pé àwọn tó ń gbé ní ìgbèríko ní àǹfààní sí ètò ìlera tó múnádóko,ó wá sọ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ agbègbè ìjọba àti aládàáni (PPCP),tí gómìnà dá sílẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tó dárajùlọ láti rí ètò ìlera tó ṣeé gbára lé gbámú ní ìpínlẹ̀ náà.
Leave a Reply