Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Kaduna tí fòfin dé gbogbo onírúurú ayẹyẹ àtí àwọn àpéjọpọ̀ tí àwọn alatilẹyin àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n bórí tàbí pàdánù nínú ìdìbò Ààrẹ àti Aṣòfin Àgbà tí Orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹṣẹ parí ní ìpínlẹ̀ náà.
Alukoro Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá, DSP Muhammad Jalinge sọ fún àwọn òníròyìn ní Kaduna.
Jalinge sọ pe, ẹnikẹ́ni tó bá fọ́wọ́ pàdà òfin náà lójú, á jẹ́yàn rẹ̀ níṣú, nítorí pé wọ́n tí ràn àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò látí ríi dájú pé ìlú wà lalaafia.
Ó wá kesi àwọn aráàlú pé kí wọ́n tèsíwájú lórí àtìlẹ́yìn wọ́n fún ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá látí ṣé ààbò ẹ̀mí àti dùkíà àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kaduna.
Leave a Reply