Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Oníṣòwò Orílẹ̀-èdè Kenya Fẹ̀hónúhàn Lórí Àwọn Àkẹgbẹ́ Wọ́n Látí Orílẹ̀-èdè China

Lekan Orenuga

0 175

Ó lé ní ẹgbẹrún àwọn oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Kenya tó ṣé ìfẹhonuhàn ní Olú-ìlú Nairobi lórí bí wọ́n ṣé lòdì sí àwọn oníṣòwò Àkẹgbẹ́ wọ́n látí orílẹ̀-èdè China.

Ifẹhonuhan náà wà ní ìbámu pẹ̀lú àríyànjiyàn pé ilé ìtàjà gbogbogbò China tí á mọ̀ sí “China Square retail outlet of General Merchandise” ń tá àwọn ọjá wọ́n lọpọ ní ìdá Ogójì àtí márùn ùn 45% sí ìdá ọgọrùn tí àwọn aráàlú ń tá tí wọ́n. Ìròyìn náà sọ

“Àwọn ará China kò lè máa kó ọjà wọ̀lé, kí wọ́n jẹ́ oníṣòwò, olùtajà, àtí olukiri-ọjà ní orílẹ̀-èdè yìí,” ọkàn nínú àwọn àkọlé àsìá tí wọ́n gbé sọ. Bákannáà ní àwọn kàn gbèé pé “Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China gbọ́dọ̀ lọ́.”

Orílẹ̀-èdè China jẹ́ alabaṣepọ ìṣòwò ní ilẹ̀ Áfíríkà àtí pé ó lé ní mílíọ̀nù kàn ọmọ orílẹ̀-èdè China tó ń gbé ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Tún kà nípa: Áà! Iná Líle Jó Igbó Kìjikìji Tó Wà Lórí Òkè Ni Orílẹ̀-èdè Kenya

Ọ̀gbẹ́ni Lei Cheng tó ní ilé ìtàjà China náà sọ fún àwọn òníròyìn pé iyé owó ọjà ní Òlú ìlú Orílẹ̀-èdè náà ló mú òún pinnu láti ṣì ilé ìtàjà lọ́nà ẹtọ náà sílẹ̀.

Ibaṣepọ Kenya pẹ̀lú China ló tí mẹ́hẹn làkókò ìdìbò gbogbogbòò tí ọdún tó kọjá, tí William Ruto bórí.

Ruto ní oṣù kọkànlá ṣé ìlérí nínú ìpolongo rẹ̀ látí ṣé àgbéjáde àwọn ìwé àkànṣe ìṣẹ́ ọkọ ojú-irin òní bílíọ̀nù Mẹ́tà dọla $3b láàárín ìjọba àtijọ àti Orílẹ̀-èdè China àti pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè China tí kó ní ìwé ìgbélú yóò pàdà sí orílẹ-èdè rẹ̀

Leave A Reply

Your email address will not be published.