Take a fresh look at your lifestyle.

Oǹkọrin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Falz Gba Àwọn Ọ̀dọ́ Ní Ìmọràn Látàrí Ìbò Tó Ń Bọ̀

0 433

 

Oǹkọrin Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti agbẹjọ́rò, Falz ti gba àwọn ọ̀dọ́ ní ìmọ̀ràn tó lè bí awọ erin látàrí ìbò ti yóò wáyé ní ọjọ́ karún ún dín lọ́gbọ̀n osù yìí.

Oǹkọrin náà lo ojú òpó ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ láti gba àwọn ọ̀dọ́ ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n jáde ní yanturu láti fi ìbò wọn gbé adarí rere wọlé.

Lórí ẹ̀rọ Fidio ayélujára rẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n máṣe ṣe àwáwí pé àwọn kòní jáde láti dìbò.

Ó rọ àwọn ọ̀dọ́ láti má jẹ́ kí ìṣòro tí orílẹ̀-èdè yìí ń là kọjá yìí pe ìpè fún wọn láti má dìbò tàbí wí pé tí wọ́n bá di ìbò, wọn kò ní ka ìbò wọn. Ìbò wọn yóò di kíkà, kí wọ́n ṣe ètọ́ àti ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn olórin miran ti ń sọ ṣáájú.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button