Ó ju ẹgbẹ̀run mẹ́rin-dín-lógún sarè ilẹ̀ igbó Kìjikìji tí iná tó lágbára ti jó run ní orí òkè ìlú Aberdare tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Kenya.
Ìròyìn fi lédè pé iná náà bẹrẹ ni agbègbè Igbó Kìjikìji tó wà ní Aberdare National Park láti ọ̀sẹ̀ méjì tó kọjá tó sì tẹ̀síwájú láì kú bótilẹ̀jẹ́pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná gbìyànjú títí láti pá sùgbón iná náà kò kú.
Àwọn ènìyàn méjì láti ọdọ àjọ Kenya Wildlife Service, KWS tó lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọjọ́ kejì kété tí iná náà ṣèyọ ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn látàrí ọkọ̀ wọn tó ṣubú síbi iná náà.
Ọ̀gbẹ́ni Bakari Mungumi láti ilé iṣẹ́ KWS so pé àwọn sí ń tẹ̀síwájú láti se ìwádìí okùnfà iná náà.
“Ọ̀gbẹlẹ̀ àti lílọ sókè afẹ́fẹ́ ni orí òkè jẹ́ kí iná náà lágbára síi; kò sì fi àyè sílẹ̀ láti tètè pa iná náà” Ọ̀gbẹ́ni Mungumi sọ èyí.
Kìí ṣe àkọ́kọ́ nìíì tí iná máa ṣọsẹ́ ní agbègbè náà, ní ọdún 2012, ó ba sarè ilẹ̀ igbó Kìjikìji tó ju àádọ̀rin ẹgbẹ̀rún jẹ́.
Aberdare jẹ́ òkè gíga kẹta ní orílẹ̀-èdè Kenya, ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ bàtà ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá lé ní ọgọ́rùn ún
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
[…] Tún kà nípa: Áà! Iná Líle Jó Igbó Kìjikìji Tó Wà Lórí Òkè Ni Orílẹ̀-èdè Kenya […]