Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Àgbẹ Ìlú Kano Kó Irè Oko Yanturu Ní Àkókò Ọ̀dá Òjò

1 299

 

Àwọn àgbẹ̀ ni ìletò Kanwa, abúlé kan tí kò jìnà púpọ̀ sí ìlú Kano ti kó ọ̀pọ̀ irè oko yanturu látàrí ẹ̀fọ́ gbígbìn.

Ọ̀pọ̀ omi adágún yí abúlé náà po tí eléyìí sì fún àwọn àgbẹ̀ ní ànfààní ẹ̀fọ́ bíi lẹ́tùsì, tòmátì, pòtátò àti àlùbósà láti gbìn ní àkókò ọ̀dá òjò.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbẹ̀ tí wọ́n gbin nǹkan oko yìí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kórè nǹkan oko wọn. Ọkan ninu wọn, Zubairu Murtala Kanwa, sọ pé òun kore apẹrẹ Tomati meje ninu oko ti ko tọ ile eka kan ni nnkan bi ọsẹ meji bayii, èyí sì ni ebi oun gbojule fún atike ati atimu.

Agbe miran, Abdullahi Auwalu sọ wí pé ọpọlọpọ wọn ni won gbẹkẹle omi adagun ni àkókò oda ọjọ, bí oun ko tilẹ ní ọkọ pupo, òun a ma pa owo to joju lori Alubosa, ojojumọ ni awọn síi n ta Letusi.

“Iyawo ati ọkan lára ọmọ mi a ma ta Letusi ati Tomati, ibe lati n ri owo awọn ọmọ ilẹ iwe san ati lati se awọn nnkan miran”.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

One response to “Àwọn Àgbẹ Ìlú Kano Kó Irè Oko Yanturu Ní Àkókò Ọ̀dá Òjò”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button