Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ń Gbìyànjú Láti Dóòlà Ẹ̀mí Lẹ́yìn Ìsẹ̀lẹ̀ Omíyalé Ní Orílẹ̀ Èdè Mozambique

1 129

Ìjọba Orílẹ̀ Èdè Mozambique ti ń wá ojútùú sí wàhálà tí àrọ̀ọ̀dá òjò tí ó fa omíyalé dá sílẹ̀ ní àgbègbè Maputo ní Ọ̀ṣẹ̀ yìí.

 

Ìròyìn abẹ́lé fi yéwa pé, kò dín ní ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ Ilé ni ó fi ara káásá níbi ìsẹ̀lẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ omi náà ba nǹkan jẹ́ ní Matola ati Boane tí ó jẹ́ àwọn Ìlú tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Maputo tí ń se olú Ìlú Orílẹ̀ Èdè náà.

 

Àríwòye wá pé irú ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún le è wáyé ní ọjọ́ iwájú, nítorí náà ni ìjọba se ń gbìyànjú láti wá ojútùú síi.

 

1 Comment
  1. […] Tún kà nípa: Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ń Gbìyànjú Láti Dóòlà Ẹ̀mí Lẹ́yìn Ìs… […]

Leave A Reply

Your email address will not be published.