Mínísítà fún ìròyìn, Àṣà,ati Ìṣẹ ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,ń ṣiṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ pẹ̀lú UNWTO, àwọn tọrọ kan, àti àwọn ilé iṣé aláàdáni láti rí wí pé wọ́n dá ilẹ́ ẹ̀kọ́ isẹ̀báyè sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Alhaji Lai mohammed ti o jẹ Mínísítà fún Ìròyìn Àṣà ati Ìṣe, ló fi erongba wọn han nibi ìfilọ́lẹ̀ ìpàdé iṣẹ̀báyé àpapọ to wáyé ní ìpínlẹ̀ Eko nínú osun kọ́nkònlá ọdún 2022.
Alahji Mohammed sọ èyí di mímọ̀ níbi ayẹyẹ àṣeyọrí ẹkọ ti àwọn ọmọ ilẹ̀ ìwé Terra Academy fún afẹ́ ṣe èyí to wáyé ni ìlú Eko ni ọjọ́ ẹtì.
Mínísítà ní ibi isẹ̀báyè yìí yóò wá ní ìlú Eko lati le jẹ kí àǹfààní ,idagbasoke, òlàjú àti ìyípadà dé bá ètò isẹ̀báyè.
Bákanáà, Olùdásílẹ̀ ilé ìwé náà , ìyáàfin Bolanle Austen-Peter to wa nikalẹ níbí ayẹyẹ náà, tẹnumọ wí pé àǹfààní wà nínú ka gbìn ìmọ̀ sínú àwọn ọ̀dọ́ .
Ó ki àwọn ọmọ ilẹ̀ ìwé náà kù oríre àṣeyọrí wọn.
Ìyáàfin Austen-Peter pari ọ̀rọ̀ rè nígbà tí ó rọ àwọn ọ̀dọ́ láti sí ọkàn sílẹ̀ fún iṣẹ́ níbikíbi kí ò lé jẹ àǹfààní fún wọn láti fi ìmọ̀ tí wọn ti gbà hàn sí àgbáyé.