Take a fresh look at your lifestyle.

Mo fẹ́ Kí Ìbáṣepọ̀ Tó Dàn Mọ́rán Wa Láàrín Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìjọba Àti Àwọn Adájọ́: Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra.

1 137

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, ọ̀mọ̀wé Chukwuma Soludo, ti pe fún Ìbáṣepọ̀ to dán mórán láàrín àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba ati àwọn olùdájó ìpínlẹ̀ náà,lati fi ayé gba àlàáfíà àti ìrépọ̀.

Níbi ibura sẹ́nu iṣẹ́, agbẹjọ́rò Etomike Ndigwe àti Fagbo Anieto gẹ́gẹ́ bí adájọ́ ìpínlẹ̀ Anambra ní Gómìnà ti pe fún Ìbáṣepọ̀ náà.

Ó kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun náà kù oríre,o sí dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun fún yíyan wọn gẹgẹ bí olùdájó tuntun fún ìpínlẹ̀ náà

Adájọ àgbà pátápátá ati kọmísọ́nà fún ìdájọ, ọ̀mọ̀wé Sylvia Ifemeje, pe àwọn olóyè tuntun mẹ́jẹ̀jì náà síta, láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ìbúra nínú ìwé òfin 271 ti odun 1999 ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

1 Comment
  1. […] Tún kà nípa: Mo fẹ́ Kí Ìbáṣepọ̀ Tó Dàn Mọ́rán Wa Láàrín Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìjọba Àti À… […]

Leave A Reply

Your email address will not be published.