Ẹni tíì ṣe Oludije du ipò Aṣòfin ti yóò ṣojú Ẹkùn Ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú ètò ìdìbò gbogboògbò to n bọ, Amofin Sharafadeen Abiodun Alli ti sọ di mímọ pé kò sí ohun tó n jẹ́ Ìjọba Ìbílè ní Ìpínlè Ọ̀yọ́, eléyìí tó fi dàbí i pé ẹka ìjọba náà ti di òkú pátápátá nítorí ìjọba Ìpínlè to wà lóde ni ìpínlè náà kò fún wọn ní anfààní láti ṣe iṣẹ wọn bíi iṣẹ.
Sharafadeen Alli, ti o ti fi ìgbà kan rí jẹ́ akọ̀wé ìjọba ni Ìpínlè Ọ̀yọ́, tí o tún ti jẹ́ Alága Ilé Iṣé Idokowo Odu’a nigba kan rí, lo sọ ọrọ yìí lásìkò tí o wà fún ifọrọwerọ pẹlú àwọn oníròyìn ní Ọfiisi wọn tó wà ní agbègbè Mokola ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ní Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nígbà tí o n ba àwọn oníròyìn sọrọ, Alli ti o tún jẹ́ Mayẹ Olúbàdàn Ilẹ Ìbàdàn, tí o sì tún ti fi ìgbà kan rí jẹ́ Alága Ìjọba Ìbílè Àríwá Ìbàdàn ló sàlàyé pé ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ko lágbára láti ṣe ohunkohun nítorí ìjọba ìpínlè kò yọnda owó fún wọn, eléyìí tó fàá ti o fi dàbí i pé kòsí ijoba ìbílè ni ìpínlè Ọ̀yọ́.
O tẹnu mọ wí pé, ìjọba ibile náà ní agbara lati din ìṣòro airise kù nípa ìpèsè iṣẹ fún àwọn ọdọ tí kò rí iṣẹ, tí ẹka ìjọba náà bá lè dá dúró láì sinmi lé ìjọba ìpínlè.
Allí wá sọ di mímọ pé òun gẹgẹ bíi ẹnikan fara mọ òfin tó fún ìjọba ìbílẹ̀ ní agbára láti dá dúró gẹgẹ bíi ẹka ìṣèjọba kí àwọn náà lè ní ànfààní láti ṣe iṣẹ́ laye ara wọn.
Bákan náà, Alli bu ẹnu atẹ lu ìjọba tó wà lóde ni ìpínlè Ọ̀yọ́ labẹ àkóso Gómìnà Seyi Makinde látari ìpèsè ètò ìlera ti kò kún tó fún ara ìlú nítorí àwọn ile ìwòsàn náà ṣe aláìní ohun èlò àti oṣiṣẹ. O wá fi àsìkò náà ṣèlérí wí pé tí òun ba wọlé gẹgẹ bíi aṣòfin ní ilé ìgbìmò Aṣofin Àgbà, òun yóò ṣe àbá’dofin, ni pàtàkì jù lọ eléyìí tí yóò sọ ilé ìwòsàn tó wà ní Igbo-ora ni ẹkùn ìdìbò Gúsù Ọ̀yọ́ di èyí tí yóò wà lábé àkóso ìjọba àpapọ̀.
O wa tun fi àsìkò náà ṣèlérí fún àwọn oníròyìn ní ìpínlè Ọ̀yọ́ wí pé òun yóò mú ìgbàyè-gbádùn ni okunkundun.
Abiola Olowe
Ìbàdàn