Ilé-iṣẹ́ Òfurufú tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní Ọjọ́rú gbá ibuwọlú ìwé iṣẹ́ àkànṣe tí ó tó ọ̀ọ́dẹ́gbẹ̀rin lé lógún mílíọ̀nù Náírà N721m fún ìtọ́jú Pápákọ̀ Òfurufú Aminu Kano International ní Ìpínlẹ̀ Kano, Àríwá Ìwọ̀-oòrùn tí orílẹ̀-èdè yìí tí yóò jẹ́ oloṣu méjìlá.
Mínísítà fún ètò ọkọ Òfurufú, Hadi Sirika, ló sọ èyí fún àwọn òníròyìn ní ìparí ìpàdé àwọn alẹnu-lọ̀rọ̀ tí Orílẹ̀-èdè yìí tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣé Olùdarí rẹ̀.
Tún kà nípa:Ààrẹ Bùhárí ń darí àpèjọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ àpapọ̀
Nínú ìdánilójú kàn, Mínísítà náà sọ pé; “Nigeria Air yóò bẹ̀rẹ̀ sí fó láìpẹ́. A tí ṣètò bàálù náà, wọ́n sì tí kùn wọ́n ní àwọ̀ wọ́n, gbogbo ló tí tó, pàápàá jùlọ ìwé àṣẹ Air Operator Certificate AOC tí àjọ Nigeria Civil Aviation Authority NCAA má ń pèsè, lẹyìn náà ọkọ Òfurufú náà yóò bẹ̀rẹ̀ síi fo,” Mínísítà náà ṣàlàyé.
Lekan Orenuga
Leave a Reply