Àjọ Tí Ó Ń Gbógun Ti Ìwà Ìbàjẹ́ Sàwárí Ọ̀ọ́dúnrún Mílíọ̀nù Owó Tuntun Ní Ilé Ìfowópamọ́ Sterling
Àjọ tí ó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà búburú míràn ti se àwárí ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù ó dín díẹ̀ owó tuntun èyí tí wọ́n kó pamọ́ ní ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ ilé ìfowópamọ́ Sterling ní ìlú Abuja.
Agbẹnusọ àjọ náà, Arábìnrin Azuka Oguagu sọ pé àsírí náà tú látàrí akitiyan àjọ náà láti ríi dájú pé àwọn ilé ìfowópamọ́ tẹ̀lé àṣẹ ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ lójúnà àti jẹ́ ki ́owó tuntun náà dé ọwọ́ ará ìlú. Eléyìí fi hàn pé ilé ìfowópamọ́ náà kùnà láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn rí owó náà gbà, léyìí tí ó sì ti mú ìnira bá ará ìlú.
Àjọ náà tún tẹ̀síwájú lọ sí àwọn ilé ìfowópamọ́ míràn bíi Keystone, Zenith, Fcmb, léyìí tí wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí ó ń kó ìfàsẹ́yìn bá ètò náà lójúnà àti fi imú wọn kó ata òfin.
Leave a Reply