Ààrẹ Buhari ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ẹsinòkọkú tó se ìkọ̀lù sí àwọn figilanté nínú igbó Yargoje ti ìjọba ìbílẹ̀ Kankara ní Ìpínlẹ̀ Katsina níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti gbẹ̀mí mì.
Àwọn ẹsin-ò-kọkú kọlu àwọn figilanté nínú Igbó níbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ gba àwọn Màálù tí wọ́n jí kólọ padà lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi kí wọ́n tó se alábàpàdé ikú òjìjì.
Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ se sọ ní ọjọ́ Àìkú láti ẹnu agbẹnusọ rẹ̀ Malam Garba Shehu, ó bẹ àwọn figilanté ati ìdílé wọn wò, ó bá wọn kẹ́dùn.
“Èrò wa àti àdúrà wa wà pẹlú ìdílé àwọn olóògbé ní àsìkò tó lágbára yìí, kí Ọlọ́run tẹ́ wọn sí afẹ́fẹ́ rere,” Ààrẹ sọ bẹ́ẹ̀.
Àwọn olùgbé sọ pé, àwọn alamí ẹsin-ò-kọkú kan tó ń gbé ní agbègbè Bakori àti ìjọba ìbílẹ̀ Kankara ló ta àwọn ẹsin -ò-kọkú lólobó pé àwọn figilanté kan ń tọ pinpin wọn, eléyìí mú kí wọn gbẹ̀yìn lọ dojú ìjà kọ àwọn figilanté náà láìròtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì gbẹ̀mí wọn.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san