Orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà Bá Orilẹ́-èdè Turkey Àti Syria Kẹ́dùn Látàrí Ìjàmbá Ilé Mímì To Ṣẹlẹ̀ Ní Orílẹ̀-èdè Méjèjì.
Ààrẹ Muhammadu Buhari tí fí ẹdun inu rẹ hàn ati ìbani kẹ́dùn sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè àti ìjọba Turkey pẹlu Syria àti àwọn tó pàdánù ebi àti ọ̀rẹ́ wọn nínú ìjàmbá ilé mímì to wáyé ni Turkish Gaziantep.
Ààrẹ gbàdúrà fún àwọn tó farapa fún àlàáfíà pípé lásìkò, ó sí fí dá wọn lójú wí pé ádùrá àti ẹ̀rọ̀ réré àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nbè pẹ̀lú wọn lakọkọ yìí.
Gẹ́gẹ́ bi àjọṣepọ̀ tó wà láàrin orílẹ̀-èdè Turkey ati Syria, ààrẹ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ṣetán láti ràn wọn lọ́wọ́ ni gbogbo ọnà tí wọn bá ti nílò ìrànlọ́wọ́.