Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti pe fun sisun gbedeke ati na owo naira tẹlẹ ti Ile Ifowopamọ agba kede siwaju di oṣu keje ọdun 2023.
Ile Aṣofin naa pe Giwa Ile Ifowopamọ agba naa, Ọgbẹni Godwin Emefiele ninu ijiroro wọn lati sun ọjọ naa siwaju di oṣu keje ọdun.
Aṣofin Rotimi Olowo (Ṣomolu ii) lo mu aba naa wa nigba ti o n yan na-an-na ipenija ti awọn ọmo orilẹ-ede Naijiria n koju bayii latari ilana ile ifowopamọ-agba CBN naa, nigba ti wọn n gbiyanju ati ko owo tẹlẹ pada, ki wọn tun to ri tuntun gba.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe ilana naa pa ọpọ ara ilu lara, paapaa awọn olokoowo kekeeke. Idokoowo lilo ẹro ifiṣe paṣipaarọ owo ti o n pese iṣẹ diẹdiẹ fun awọn ọdọ naa ti n dẹnu kọlẹ latari ilana yii.
O ṣalaye pe imọ-ẹrọ ayelujara orilẹ-ede yii ko ti i fẹsẹ mulẹ. O ni:
“Bo tilẹ jẹ pe erongba ilana yii dara lati ṣadinku iwa ibajẹ, ṣugbọn ipalara rẹ pọ pupọ ju lara awọn ara ilu. Awọn to rọwọ mu lawujọ nikan ni ilana naa gbe”
Awọn to kin aba naa lẹyin ni Aṣofin Bisi Yusuf, Aṣofin Makinde, Aṣofin Meiranda, Aṣofin Oluwa, Aṣofin Kasumu, Aṣofin Idimogu, Aṣofin Akandeati Aṣofin Setonji, ti wọn fẹdun ọkan han si inira ti ilana CBN naa n mu ba awọn ara ilu eleyii to ju anfani rẹ lọ. Wọn ni:
“Awọn ẹni to ri jajẹ laarin ilu ni awọn ile-ifowopamọ yii n ta awọn owo tuntun yii fun nigba ti awọn mẹkunu lorilẹ-ede Naijiria n jiya rẹ. Inu wa ko dun nitori pe, ọpọ awọn ara ilu ni ilana yii n pa lara. Ko si ile ifowopamọ ti ẹrọ wọn ṣiṣẹ lati fun awọn onibaara lowo bayii.”
Oludari Ile Aṣofin Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa yin awọn ara rẹ fun iru ọrọ to kan ara ilu ti wọn mu lọkunkundun bayii. O ni:
“Ohun to jẹ ẹdun ọkan wa ni ti ipalara ti ilana naa ti mu aba awọn ara ilu. Iwulo ilana naa ko ni eso rere, nitori pe ki wọn to ṣe iru ilana bẹẹ, o yẹ ki wọn fọrọ lọ awọn to yẹ gbogbo.
“A gbori yin fun ile Igbimọ Aṣofin Apapọ fun ipa ti wọn sa lati le sun gbedeke ọjọ ti wọn fun fifi opin si nina owo tẹlẹ naa, ti wọn fi sun un fun ọjọ mẹwaa, ṣugbọn eleyii ko to rara. Fun idi eyi, ki Ile Aṣofin naa si ṣe e ki wọn le sun un di oṣu kẹfa ọdun yii.”
Leave a Reply