Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Asiwaju Bola Ahmed Tinubu Ló Lè Ṣe Àkóso Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà Láì Fi Ti Ẹ̀sìn Tàbí Ẹ̀yà Ṣe: Alhaji Abduljelili Adesiyan

0 92

Alága Ìgbìmò ìdìbò abẹle fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni Ìpínlè Ọ̀yọ́, Alhaji AbdulJelili Adesiyan, tí o ti fi igba kan ri jẹ Mínísítà fún òrò to ní ṣe pẹlu ile iṣẹ olópàá ni Orílè èdè Nàìjíríà tí sàlàyé wí pé Asiwaju Bola Ahmed Tinubu nìkan ni oludije tó tayọ láàrin gbogbo àwọn tó n dije du ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú kan tàbí òmíràn.

Adesiyan tí o tun jẹ ọkan lára ìgbìmò ìpolongo ibo Ààrẹ fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lo sọ ọrọ yìí lásìkò tí o n ṣe iforowero pẹlu àwọn oníròyìn ní ilé ẹgbẹ wọn tó kalẹ sí àgbègbè Mokola ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlè Ọ̀yọ́ ní Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Nínú ọrọ àkóso rè, Adesiyan jẹ kí o di mímọ fún àwọn oníròyìn wí pé Asiwaju Tinubu tí o ti fi ìgbà kan rí jẹ Aṣòfin ni ilé ìgbìmò Asofin Àgbà Orilẹ èdè Nàìjíríà, tí o sì tún ti fi ìgbà kan ri jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ló ní ìrírí tí o sì mọ t’inu tòde òṣèlú ti yóò lè di àlàfo tó wà láàrin àwọn tó lówó àti àwọn ti kò ní tó láì fi ti ẹsin tabi ẹlẹyamẹya ṣe.

Nígbà ti o bù ẹnu atẹ lù igbesẹ ìjọba àpapọ lórí afikun owó epo bentiro àti ayípadà owó náírà ni irú àsìkò bíi èyí tí ètò ìdìbò gbogboògbò n kan l’ẹkun, eléyìí to mu ìnira dé bá ọmọ orílẹ̀-èdè yìí latari ọwọn gogo epo àti ìṣòro àìrí owó náírà tuntun gbà ní àwọn ilé ifowopamọ, Adesiyan wá sọ pẹlu ìdánilójú pé gbogbo nkan wọnyii ni Asiwaju Tinubu yóò wá àtúnṣe sí ti o bá di Ààrẹ orilẹ èdè Nàìjíríà.

O wa fi àsìkò náà ké sí gbogbo ọmọ Ìpínlè Ọ̀yọ́ àti ọmọ orilẹ èdè Nàìjíríà lápapò láti tù yaaya ni ọjọ Karundinlogbon oṣù yìí láti di ibo wọn fún Asiwaju Tinubu ti ẹgbẹ òṣèlú APC gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bákan náà lo tún ro gbogbo ọmọ bíbí àti olùgbé Ìpínlè Ọ̀yọ́ láti rí dájú wí pé wọn di ibo wọn fún Olóyè Teslim Folarin ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Ìpínlè Ọ̀yọ́ tó bá di ọjọ́ Kọkànlá oṣù kẹta ọdún yìí kí gbogbo ohun tí ọmọ orílẹ̀-èdè yìí n pongbẹ rẹ ba lè tó wọn lọwọ.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.