Àwọn adarí agbègbè ti pè fún ìdádúró ìjà láàrin gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ní Ilà oòrùn Democratic Republic ti Congo ní kíákíá.
Rògbòdìyàn ti ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ ogun bí Congo àti alábàágbé rẹ̀, Rwanda ṣe ń fi ẹ̀sùn gbígbè lẹ́yìn ọmọ ogun kàn wọ́n.
Ìfòpinsí yìí wáyé nínú àfẹnukò níbi ìparí ìpàdé agbègbè Ilà oòrùn Áfíríkà, (EAC),ní Burundi.
Akọ̀wé gbogbogbòò ti EAC, Peter Mathuki, sọ pé, “oníkálùkù gbọ́dọ̀ tọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọsọ”.
Losù tó kọjá Rwanda tàbọn mọ́ ọkọ̀ òfurufú Ológun Congo,ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ó rúfin pápá òfurufú òun.