Àlùfáà Johnson Suleman, gbajúgbajà ìránṣẹ́ ọlọ́run tí ó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà,tí ó tún jẹ́ ààrẹ ìjọ Omega Fire, ti gba àwọn ọmọ Nàìjíríà nímọ̀ràn pé kí wọ́n dábòbò ìbò wọn lásìkò ìdìbò gbogbogbòò.
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà, tí ó fi ìmọ̀ràn yìí sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀, wá gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú láti ri pé wọ́n ṣe ojúṣe wọn nínú ìdìbò gbogbogbòò 2023.
Ó sọ pé ìdábòbò ìbò ṣe pàtàkì láti ríi pé kò sí ojúṣàájú nínú èsì ìbò.
Suleman sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ní láti tú yáyá,tú yàyà lọ dìbò ní àwọn ibùdó ìdìbò jákèjádò orílẹ̀-èdè,kí wọ́n sì dúró fún ìbò kíkà àti ìgbé èsì ìbò sáfẹ́fẹ́.
Leave a Reply