Alákóso Manchester City , Pep Guardiola sọ pé agbábọ́ọ́lù, Erling Haaland yóò rí ìlọsíwájú tí ó bá ń wò àti kọ́ṣe láti ara ẹnìkejì rẹ̀ ti Tottenham Hotspur ,Harry Kane, ní ìgbáradì fún ìfigagbága Premier League, ní ọjọ́ Àìkú, ní pápá ìṣere Tottenham Hotspur,ní London, England.
Haaland, tí ó ti gbá bọ́ọ̀lù mẹ́èdọ́gbọ̀n sínú àwọ̀n nínú ìfigagbága Premier League,ó kópa ní ẹ̀èmọkàndín-lógún,tí ó sì gbá mẹ́ta sínú àwọn Wolverhampton Wanderers, ní ìparí ọ̀ṣẹ̀ tó kọjá. Ṣùgbọ́n Guardiola sọ pé, ọmọ bíbí Norway ọ̀hun le ṣe dáradára ju bẹ́yẹn lọ, tí ó bá fojúsí bí irúu agbábọ́ọ́lu Kane ṣe ń ṣe.
Kane, tí ó gbá bọ́ọ̀lù sínú àwọn lẹ́èmẹrìn-dínlógún nínú league, jáwé olúborí níbi ìfẹsẹ̀lusẹ̀ pẹ̀lú Tottenham,pẹ̀lú àmì kan sí òdo, ní Fulham,lọ́sẹ̀ méjì sẹ́yìn láti dọ́gba pẹ̀lú olóògbé Jimmy Greaves ,tí ó fìgbà kan gbá bọ́ọ̀lù meérinlá -dín -ní ọ́rin-lé-nígba sínú àwọ̀n fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà.