Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ fi owó Náírà tuntun síta fún àwọn ará ìlú

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 216

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti pè fún ìpèsè owó Náírà tuntun síta jákèjádò orílẹ̀-èdè fún ìrọ̀rùn títà-rírà àwọn ará ìlú àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìlànà ìpààrọ̀ owó.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé pẹ̀lú ẹ̀ka ààbò olùrajà, ti ilé-ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà CBN,ní Ìlọrin, tí Ìyááfin  Rashidat Jùmọ̀kẹ́ Monguno darí,Gómìnà pè fún ìfarabalẹ̀ kí àwọn tó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀ sì ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

AbdulRazaq sọ pé òun dúpé fún àbẹ̀wò náà, tí ó sì tún ń fi dáwọn lójú pé ìjọba yóò túnbọ̀ mú àwọn ará ìlú,ilé-iṣẹ́ ìbílẹ̀,àwọn akẹ́kọ̀ọ́,gbogbo ẹ̀ka agbègbè,àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ilé-iṣé tí kìí ṣe tìjọba mọ́ra láti polongo fún ìlànà tí kò lábàwọ́n.

Ó wá  pè wọ́n níjà láti sa gbogbo agbára wọn lórí kí owó Náírà tuntun fi wà lárọwọ́tó, nítorí pé àwọn ènìyàn Kwara ń jìyà nítorí ìṣòro yìí.

Leave A Reply

Your email address will not be published.