Olùdarí Àgbà tí Voice of Nigeria, VON, Osita Okechukwu sọ pé pèlú ìfilọ́lẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ àwọn olúdìbò (Bimodal Voters Accreditation System) BVAS, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò yàn olubori nínù ètò ìdìbò gbogbogbò 2023.
DG sọ èyí làkókò tó ń mójú tó ètò idibo igbaradi ní àwọn ẹ̀kà ilé ìdìbò èyí tí Ìgbìmọ̀ élétó ìdìbò tí orílẹ̀-èdè yìí INEC, ní Abùjá.
Tún kà nípa:INEC Tí Bẹ̀rẹ̀ Sí Gbà Orúkọ Àwọn Oníròyìn Lórí Ayélujára Fún Ìdìbò Gbogbogbò 2023
Ọ̀gbẹ́ni Okechukwu tó sọ asọye lórí ìgbékàlẹ̀ tí ẹrọ BVAS, ṣé àkíyèsí pé, yóò ṣé ìrànlọ́wọ́ fún ìgbìmọ̀ náà láti fí ọkàn àwọn àrà ìlú bálẹ̀ lórí ètò ìdìbò tó múná dóko.
Nínú àwọn ọrọ rẹ̀, “Ó ní pẹ̀lú òun tí òún rí, yóò ṣóró fún ẹnikẹ́ni látí gbọ̀nà èrú jáwé olubori nínù ètò ìdìbò gbogbogbòò tó ń bọ̀ yìí. Ó sí gbóríyìn fún Ààrẹ bí ó ṣé fọwọsi ẹrọ BVAS lábẹ́ òfin. Ìyẹn nipé ìwé òfin ètò ìdìbò 2022.
Lekan Orenuga
Leave a Reply