Take a fresh look at your lifestyle.

Lagos City Marathon 2023: Eléré ìje Ọmọ Orílẹ̀-èdè Kenya Bórí Ìdíje Èrè

0 403

Edwin Kibet Koech tí orílẹ̀-èdè Kenya tí jáwé olubori nínù ìdíje tí Access Bank Lagos City Marathon ẹlẹẹkẹjọ irú rẹ̀ tó wáyé ní Lagos, Nigeria.

Ìdíje Ere-ije 42km náà bẹ̀rẹ̀ ní pápá ìṣéré orílẹ̀-èdè ní Surulere o sí parí sí Eko Atlantic ní Victoria Island.

Kibet bórí àwọn akẹgbẹ rẹ̀ tó lé ní ọ̀ọ́dúrún ní ọdún yìí pẹ̀lú àkókò 2:14:06s ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta. Dekeba Shefa tí Etiopia wà ní ipò Kejì pẹ̀lú àkókò 2:14:54s tí Bernard Sang Kenya mìíràn pẹ̀lú àkókò 2:17:14s.

Kibet ọmọ ọdún mọkandinlogoji bórí èrè ogójì lè méjì kilomita 42km ó sí gbá ẹbùn owó $50,000 fún ipò àkọ̀kọ̀, Shefa gbá ẹbùn owó $40,000 àtí Sang ní $30,000.

Ní ìpele tí àwọn Obìnrin, olubori ọdún 2018, Alemenseh Guta tí Ethiopia, pẹ̀lú àkókò 2:40:42, Kebene Urisa gbá ipò Kejì ní 2:40:44 àtí Naomi Maiyo tó ṣé ipò kẹta ní ọdún 2022 tún gbà ipò kẹta pẹ̀lú àkókò 2:40:56.

Àwọn Olubori tí ere-ije Ọkùnrin àti Obìnrin ní wọ́n tí peregede látí kópa nínú ere-ije ní Olimpiki 2024 ní Ìlú Paris.

Gyang Nyango ní ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ parí pẹ̀lú àkókò 2:27:15s. Nígbà tí Nyango gbá ìyè owó mílíọ̀nù mẹ́tà N3m fún akitiyan rẹ̀, Adamu Muazu tó wà ní ipò Kejì yóò gbà Mílíọ̀nù méjì N2m àtí Friday Yohanna tó gbá ipò kẹta pẹ̀lú àkókò 2:33:02s yóò gbá mílíọ̀nù kàn Náírà N1m.

Bákannáà ní fún ìsọri àwọn Obìnrin pẹ̀lú ẹní àkókò Deborah Pam ní àkókò 2:49:33, Elizabeth Nuhu pẹ̀lú 3:00:20 ní ipò Kejì àti Dimatu Yahana pẹ̀lú àkókò 3:02:12 ní ipò kẹta.

Ìdíje náà ló tí gbà ààmì góòlù lẹyìn ìdíje méje tí wọ́n sì ǹ gbèrò òun èlò fún ààmì Platinum. Ọkàn nínú àwọn ìbéèrè fún ààmì Platinum ní kí olùdíje sáré ìṣẹjù 2:10 fún ìdíje àwọn ọkùnrin àti iṣẹju 2:13 fún àwọn Obìnrin ṣùgbọ́n kò lé ṣeéṣe lọdún yìí nitori pé ó kú iseju mẹ́rìn 4s père kí Kibet fí mú ìdíje náà peregede. Ìyẹn túmọ sí pé, wiwà ìdàgbàsókè fún ìdíje náà sì ń tèsíwájú.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button